BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí BBC rèé lórí ẹ̀sùn àjẹbánu ₦44m táwọn aṣòfin Ondo fi kan Olórí ilé tí wọ́n fi ni kó fipò sílẹ̀
Awọn aṣofin naa fun olori ile aṣofin ti i ṣe Abẹnugan wọn; Olamide Oladiji,ni gbedeke di ọjọ Aiku, ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2026 lati kọwe fipo rẹ silẹ bibẹẹkọ awọn maa yọ nipo.
Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin buwọ́lu àbádòfin fún ìdásílẹ̀ ọlọ̀pàá ìpínlẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà
Eyi waye l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun oṣu Keje ọdun 2026 yii.
Wo ìdí tí Trump ṣe kọ lẹ́tà, kan sáárá sí Tinubu lórí gbígbógun ti ìgbéṣúmọ̀mí
Agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga ninu atẹjade kan to fi soju opo X rẹ ni Trump kan saara si Tinubu lorukọ awọn ọmọ Naijiria.
Bí iléẹjọ́ ṣe dá EFCC lọ́wọ́ kọ́ láti ṣe ìwádìí ìṣúná gómìnà Oyo, ẹgbẹ́ APM ní ẹ̀rù Makinde ló ń ba Tinubu
EFCC lo gbe akanṣe iwadii dide lati ṣe agbeyẹwo awọn owo iṣẹ akanṣe ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe jáde.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,01
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Fídíò, Wo ewu tó wà nínú kí èèyàn máa fi ẹsẹ̀ lásán rìn tàbí gbé bàtà tí o bá wọ́ jáde, wọnú ilé padà , Duration 2,35
BBC News Yorubá tọpinpin ọ̀pọ̀ ewu tó wà nínú kí èèyàn máa fi ẹsẹ̀ lásán rìn tàbí gbé bàtà tí o bá wọ́ jáde, wọnú ilé padà.
Fídíò, Ohun tí BBC rí rèé níbùdó tí wọn ti ń po kẹ́míkà pọ̀ lọ́nà àìtọ̀ tó tó $400m táwọn ọmọ ilẹ̀ Mexico ń ṣe, Duration 1,46
Iléeṣẹ́ BBC lọ sí ibùdó tí wọn ti ń po kẹ́míkà pọ̀ lọ́nà àìtọ̀ èyí tó tó ₦400m táwọn ọmọ ilẹ̀ Mexico ń ṣe, ẹ wa wo ọ̀pọ̀ ohun àwòdamiẹnu tí a rí níbẹ̀.
Aláànú kan kéde láti ṣe alágbàtọ́ láéláé fún ọmọ mẹ́ta tí John Olaleye bí, olùkọ́ táwọn ajínigbé pa ní Oriire
Dokita Kunle Adegbite kede wi pe nipasẹ ajọ alaanu Twindad Foundation loun yoo fi ṣe alagbatọ awọn ọmọ mẹta naa ti orukọ wọn n jẹ Daniel, Joy ati Morayo Olalere.
ICPC ṣàwárí ayédèrú òṣìṣẹ́ 908 láwọn iléeṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà àádọ́ta, ọlọ́pàá pọ̀ nínú wọn
Alaga ICPC, Musa Adamu Aliyu (SAN) fidi eyi mulẹ fun BBC.
Àtakò dìde lórí àlàyé ikú tó pa ọ́gágun Sani Abacha tó gba orí ayélujára, àlàyé rèé
Latigba ti iku Ọgagun Abacha ti jade sita, ni airyanjiyan ti wa kaakiri agbaye, paapaa nilẹ Naijiria to ti jẹ adari, ti awọn eeyan ko si gbagbe titi di asiko yii.
Kí ni ipa tí ìdásílẹ̀ ibùdó ológun tuntun ní Omu-Aran, Kwara, yóò ní lórí àwọn ajínigbé, àgbésùnmọ̀mí àti aráàlú? Àwọn onímọ̀ sọ̀rọ̀
Atẹjade kan ti Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq fi soju opo X rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kọkanlelogun, oṣu Keje sọ pe ilu Omu-Aran ni ijọba ibilẹ Irepodun ni ibudo ọmọ ogun naa maa wa.
Ọkùnrin tó gbé aláìsàn wá sílé ìwòsàn Adeoyo n'Ibadan yarí pé kò sí dókítà lẹ́nu iṣẹ́, ó yájú sí Nọ́ọ̀sì, ẹgbẹ́ àwọn Nọ́ọ̀sì fọnmú
Loju ẹsẹ ti wọn sọ fun ọkunrin naa pe ko si dokita lẹnu iṣẹ ni alẹ ọjọ naa, lo ti sọ ọrọ ọhun di ariwo, to si bẹrẹ sii ṣe ikọlu si nọọsi to ba lẹnu iṣẹ.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Wo àwọn nǹkan tí Andy Burnham, Olóòtú ìjọba UK tuntun lóun yóò ṣe fún ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Nigba to n ṣalaye ipinnu ati erongba rẹ fun ilẹ Gẹeṣi, Burnham sọ pe bi orilẹede United Kingdom yoo ṣe duro ṣinṣin lo mumu laya oun to si jẹ oun logun julọ. Andy to jẹ Olootu keje fun UK lati 2016, sọ pe asiko ironusi bi nnkan ṣe n lọ ni U
Iyabo Obasanjo àti olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ APC l‘Ogun, Yayi, ń tutọ́ síra wọn lójú
Yayi lo n fun Iyabo Obasanjo lesi lẹyin ti Obasanjo fẹsun kan pe Yayi ko ṣe awọn nnkan to ṣeleri rẹ fun oun leyin ti oun gba pe ki wọn panupọ fẹnuko lati yan-an bi oludije sipo gomina lẹgbẹ APC.
Àwọn oníjìbìtì orí ayélujára tọwọ́ bọ ojú òpó Ààrẹ Kenya, wọ́n ń bèèrè $320,000
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti I sẹni to mọ awọn onijibiti ori ayelujara to ṣiṣẹ naa.
Afurasí tíṣà tí wọ́n ló lu akẹ́kọ̀ọ́ pa jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ọlọ̀pàá
Iṣẹlẹ naa waye niluu Adazi- Ani, nijọba ibilẹ Anaocha, ipinlẹ Anambra.
Àṣìta ìbọn agbésùnmọ̀mí pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lásìkò táwọn ológun ń dènà ìjínigbé
Aṣita ibọn pa awọn akẹkọọ naa nigba ti awọn agbesunmọmi kọlu ile ẹkọ wọn lọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlogun oṣu Keje ọdun 2026 yii.
Àdó olóró Iran ṣekúpa ọmọ ogún Amẹ́ríkà méjì, ìkọlù bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun
Ileeṣẹ aabo Amẹrika, US Central Command, Centcom sọ pe awọn ọmọ ogun Amerika ṣekọlu sawọn ileeṣẹ Ologun naa, ti ileeṣẹ iroyin Iran naa si fidi rẹ mulẹ pe Amẹrika ṣekọlu si Qeshm Island to wa ni odo Strait of Hormuz.
Ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni tako òfin tó sọ ọ́ di èèwọ̀ láti máa wàásù nínú ọkọ̀ akérò
Ofin naa ni ẹnikẹni to ba jẹbi ṣiṣẹ bẹẹ yoo san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bii owo itanran tabi ko fi ẹwọn jura.
Ìdí rèé tí ìgbéyàwó èmi àti Ayinla Kollington ṣe forí ṣánpọ́n - Salawa Abeni ṣàlàyé
Lẹyin ọdun kan o le diẹ ti Kolington to sọrọ naa ni Salawa to fi ọrọ rẹ tirẹ lede ninu ifọrrọwerọ kan pẹlu Oyinmomo TV.
Ajínigbé yọ̀ǹda òkú ìyá, dẹ́rẹ́bà àti ọ̀kan lára ọmọ ìyá mẹ́ta tí wọ́n jí gbé, bèèrè N30m
Saaju ni a ti fi to yin leti pe awọn ajinigbe gbe awọn eeyan naa lasiko ti wọn n rin irinajo lati Abuja si Okelenyi, ipinlẹ Benue lati sin oku iya wọn.
Mọ̀ nípa ìtàn ife ẹ̀yẹ àgbáyé àti òdiwọ̀n góòlù tí wọ́n fi ṣe ife ẹyẹ ọdún 2026
Akọsilẹ fi han pe o to $713,000 (£532,000)
Wo ìdí tí ECOWAS ṣe fòǹtẹ̀ lu ríri ọ̀pá gáàsì láti Nàìjíríà lọ Morocco dé Yúróòpù, àti ìpè láti kọjú oro sí South Africa lórí àtakò rẹ̀ sáwọn adúláwọ̀ míì
Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu sọ pe ti awọn olori orilẹ ede Africa ba kọ lati dakẹ, ti wọn ko ba gbiyanju pana aawọ, o ṣeeṣe ko mu alekun ba aisi igbọra ẹni ye nilẹ Africa.
Wo ẹ̀sùn mẹ́wàá tí wọ́n fi kan àwọn afurasí tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé l'Ogbomoso
Bi wọn ṣe fi Abdulrazak Umar ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu Khalifa/Abu Khalid) han ni wọn gbe Yunusa Musa ati Shamsu Adamu ti wọn tun n pe ni Abu Itisar wa sile ẹjọ naa lati sọ ti ẹnu wọn.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ilé aṣòfin Amẹrika buwọ́lù àbá láti dá ìrànwọ́ Amẹrika fún Naijiria dúró títí tíjọba yóò fi wá ojútùú sí ìṣekúpani àwọn Kristẹni
Aṣofin Gregory Stuebe to n ṣoju ẹkun Florida lo da aba naa l'Ọjọru ki gbogbo ile to gba a wọle.
Wo bí 'Muhammad' ṣe di orúkọ tí wọ́n ń sọ ọmọkùnrin jùlọ ní England àti Wales
Abọ iwadii ti ajọ to n ri si onka ni UK iyẹn UK Statistics Office lo fidi eyi mulẹ ninu iwadii kan ti won ṣe nipa orukọ tawọn obi fun ọmọ wọn julọ lọdun to kọja.
Aisha Achimugu, bọ̀rọ̀kìnní obìnrin tí iléẹjọ́ gbẹ́sẹ̀lé ẹ̀ṣọ́ ara àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí owó rẹ̀ tó ₦8.9bn lẹ́yìn tí EFCC fí ẹ̀sùn kíkọ́rọ̀ jọ lọ́nà èrú kàn án
Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ Naijiria, EFCC wọn fidi iroyin naa mulẹ f'awọn akọroyin lẹyin ti idajọ naa waye lori ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan an.
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ọkọ̀ bọ́ọ̀sì tó ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ ogún
Awọn alakoso orileede Uganda sọ pe yatọ si awọn akẹkọọ ogun ti wọn ba ijamba naa lọ, agbalagba kan ku, bẹẹ ni awọn miran tun farapa yannayanna ni agbegbe Kapchorwa.
Ohun tí a mọ̀ nípa ikú ọ̀dọ́bìnrin Mary Habila, òṣíṣẹ́ Mínísítà David Umahi tí wọ́n ló kú sílé rẹ̀
Iroyin sọ pe Mary, ọmọ bibi ipinlẹ Kaduna, ku lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2026, nile David Umahi, nigba to de si Ebonyi lẹyin irinajo ti oun ati ikọ olutọju minisita naa jọ rin.
Wo àwọn nǹkan tí o kò kà kún tó lè dí ojú òpó Wi-Fi rẹ lọ́wọ́ àti ọ̀nà àbáyọ
Oju opo Wi-Fi yii ni ohun to n so eeyan pọ mọ itakun agbaye, to n mu ayelujara si gbogbo ibi ti eeyan ba ran an lọ.
Òjò yóò rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́wàá gbáko – Àyẹ̀wò ojú ọjọ́
Omiyale tete maa n waye nipinlẹ Eko latari bo ṣe sunmọ eti omi, paapaa alagbalugbu omi okun Atlantic Ocean.
Wo àwọn orílẹ́-èdè ilẹ̀ Afirika táwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹrika kò gbọdọ̀ lọ
Amẹrika sọ pe ipele kẹrin ni awọn orileede mẹtalelogun ọhun wa ninu awọn orileede ti Amẹrika sọ pe awọn araalu ko gbọdọ lọ, fun idi eyi, wọn ni ko si idi pataki ti kan ti awọn eeyan fi gbọdọ lọ sibẹ.
Ohun tí a mọ̀ nípa bí Boko Haram àti ISWAP ṣe ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ AI fún ìgbésùnmọ̀mí
Iwadii ti fi han pe awọn Boko Haram ati ISWAP ti n lo AI, imọ ẹrọ to fẹrẹ ma si ohun ti ko le ṣe bi eeyan ba bẹ ẹ lọwẹ.












































































