close
Jump to content

Akọrin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Singer)
BERJAYA
American musicians Joan Baez and Bob Dylan performing at the March on Washington in 1963.

Akọrin, Olórin tàbí Ònkọrin ni ẹni tí ó ṣe àpilẹ̀kọ orin, darí orin tàbí kọ orin fún ìgbádùn àti ìfidánilárayá gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. [1][2] Akọrin lè jẹ́ olùkọ orin sílẹ̀ yálà lílé ni tàbí ègbè fún àwọn elégbè láti gbèé. Ònkọrin ma ń jẹ́ adarí orin lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tí wọ́n bá ń kọrin lọ́wọ́. Akọrin nígbà míràn a máa mú irúfẹ́ ẹ̀yà orin kan tàbí ìlanà orin kan láti máa fi gbé èrò rẹ̀ jáde fáráyé rí. Oríṣiriṣi nkan ló ma ń ṣe sábàbí àgbékalẹ̀ orin ònkọrin, èyí lè jẹ́ : ọ̀làjú, ìmọ̀ ìbílẹ̀ abínibí, àṣà, èdè, ìròrí, àwùjọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ònkọrin tí ó bá ń gbé àwo orin jáde fáráyé gbọ́ ní wọ́n ń pè ní agbóri-jáde.[3] Nígbà tí a lè pe ẹni tí ó bá ń kọ orin fún eré sinimá, eré orí-ìtàgé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní akọrin lásán. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ẹnìkanṣoṣo lè ní ànfàní láti jẹ́ akọrin, agbóri-jáde, adarí orin àti akọrin lásán.

Ìsọ̀rí àwọn akọrin

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
BERJAYA
Russian composer Igor Stravinsky in Zurich, 1961.

Ẹni tí a pè ní akọrin níbí lè jẹ́ ẹni tí ó ma hun orin pọ̀ tí ó sì ma ń kọọ́ sílẹ̀ fún kíkọ yálà nínú sinimá ni tàbí eré orí-ìtàgé àti eré àgbéléwò. Àwọn tí wọ́n ma ń kọ orin fún gbígbé àwo jáde ni a lè pè ní ònkọrin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.


Adarí otin ni ẹni tí ó ma ń darí ohùn orin pàá pàá jùlọ bí wọ́n ṣe ma ń darí àkójọpọ̀ àwọn olórin tí wọ́n kọrin lẹ́ẹ̀kan náà nípa fífi ọwọ́ darí ohùn orin wọn. Èyi wọ́pọ̀ lọ́dọ̀ àwọn gẹ̀ẹ́sì.[4] Adarí orin yìí yóò dúró lókèèrè níbí tí àwọn olórin náà ti lè ri ọwọ́ tàbí ojú rẹ̀ bí ó ṣe fi ń darí wọn.

Ni ẹni tí ó ma ń kọrin fún àwọn ènìyàn láti fi dá wọn lárayá

Àwọn agbórin-jáde kópa pàtàkì nínú bí orin ti ń dún tàbí dùn léti olùgbọ́ orin, àwọn ni wọ́n ma ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú akọrin tàbí olórin lórí ọ̀nà tí ó lè gbé orin rẹ̀ gbà tí yóò fi dùn-ún gbọ́ léti. Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni wọ́n sábà ma ń jẹ́ níbi iṣẹ́ orin kíkọ.


Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]